YBH 587

Jesu t’ O wa l’ oke-orun

Save
1. Jesu t’ O wa l’ oke-orun,
Sokale d’ enia, o ku;
Ninu Bibeli l’ a le ri,
Bi On iti ma se rere.
2. O nkiri, O sin se rere,
O nla ‘ju awon afoju;
Opo awon t’ o si yaro,
O sanu won, O si so won.
3. Ju wonni lo, O wi fun won,
Ohun wonni t’ Olorun fe;
O si se Enit’ o tutu;
Yio si gbo t’ awon ewe.
4. Sugbon iku t’ O ku buru,
A fi ko ‘ri agbelebu;
Owo rere t’ o se nkan yi,
Nwon kan mo ‘gi agbelebu.
5. O mo b’ enia ti buru,
O mo b’ iya ese ti ri,
Ninu anu Jesu wipe
On O gba iya ese je.
6. Be l’ O ku nitori ‘yi na,
O d’ enia k’ O ba le ku,
Bibeli ni, O t’ orun wa,
K’ O le dari ese ji ni.
7. Olorun, O si f’ ese ji
Awon t’ o ronupiwada;
Je k’ a ji kutu w’ oju Re,
K’ a si gba ekun ore Re.

Tip: double-tap the words (or use ) to show them full screen on a projector or TV.

My melodies

Found another hymn whose tune fits this one? Save it here so you can sing it again.

Sign in to save melodies

Sources: acknowledgements.

Take FaceChrist everywhere

Chat, post, meet people and sell from your phone. Get instant alerts for new messages and matches, plus the Bible offline in seven languages.