YBH 561

Ese t’ onigbagbo mberu?

1. Ese t’ onigbagbo mberu?
Kini ‘ba ma da won l’ amu?
Iku Jesu le ‘foya lo,
O mu isimi sokale.
2. Kil’ olori edun okan?
Kini gbogo eda ntoro,
Lehin iye ainipekun
Ti Jesu ti f’ awon Tire?
3. Aimo daju onigbagbo
Li o mu iyemeji wa;
Jesu masai f’ ara Re han,
K’ O s’ oro itunu fun wa.
4. O ko ko lati f’ ara han
Om’-odo alaigbagbo ni,
Nigbat’ o r’ iho owo Re,
Lojukanna, o jewo Re.
5. A mo p’ Olugbala ni O
T’ a ran lati gba eda la;
Sugbon fun wa n’ itelorun,
Pe, O ti gba wa la pelu.
6. Ao dagbete f’ eru gbogbo,
Idamu wa yio si fo lo,
Nigbat’ a ba mo daju pe,
‘Gbala Re ti te wa l’ owo

Tip: double-tap the words (or use ) to show them full screen on a projector or TV.

My melodies

Found another hymn whose tune fits this one? Save it here so you can sing it again.

Sign in to save melodies

Sources: acknowledgements.

Take FaceChrist everywhere

Twelve complete Bibles offline - English, French, Spanish, Portuguese, Yoruba, Hausa and Nigerian Pidgin - with reading plans, the hymnals, liturgy, church locator, groups and your church news, even when the network is poor.