Jesu, nigba aiye Re
1. Jesu, nigba aiye Re,
O ko dekun wo arun;
Igbe irora aisan
Ko kan O k’ o bo ‘le ri.
O ko dekun wo arun;
Igbe irora aisan
Ko kan O k’ o bo ‘le ri.
2. Oju anu Re ko gba
K’ elese ma je ‘rora,
B’ o tile je pe ‘ya na
To si i fun ese re.
K’ elese ma je ‘rora,
B’ o tile je pe ‘ya na
To si i fun ese re.
3. Ninu ija ki emi
Le bo l’ owo iparun,
O ko gbagbe p’ alafia
To s’ eran ara pelu.
Le bo l’ owo iparun,
O ko gbagbe p’ alafia
To s’ eran ara pelu.
4. B’ alaisan ijo wa wo
Lor’ akete irora,
Onisegun Ododo,
Se awotan arun re.
Lor’ akete irora,
Onisegun Ododo,
Se awotan arun re.
5. F’ opo itunu fun u,
K’ o le gbe ara le O,
K’ o mo pe Iwo nikan
L’ O le pa, l’ O le gbala.
K’ o le gbe ara le O,
K’ o mo pe Iwo nikan
L’ O le pa, l’ O le gbala.
6. Ma je k’ o siyemeji,
Ki irora mu bo ‘hun,
Fun l’ ebun lati wipe,
“B’ iye, b’ iku, ife Re.”
Ki irora mu bo ‘hun,
Fun l’ ebun lati wipe,
“B’ iye, b’ iku, ife Re.”
7. K’ o le wu O lati wo
Alaisan ijo wa san,
Bi beko, awa mo pe
Fun rere ni ife Re.
Alaisan ijo wa san,
Bi beko, awa mo pe
Fun rere ni ife Re.
Tip: double-tap the words (or use ) to show them full screen on a projector or TV.
Sing to the tune of
Any of these hymns' tunes fits YBH 560.