Oluwa, Iwo l’ awa npe
1. Oluwa, Iwo l’ awa npe,
A kunle siwaju ‘te Re,
Nibo l’ alailera ‘ba lo,
‘Wo nikan ni nwon le kepe.
A kunle siwaju ‘te Re,
Nibo l’ alailera ‘ba lo,
‘Wo nikan ni nwon le kepe.
2. Oluwa, awa yipada
S’ odo Re t’ a ti ko sile;
Jo, da ilu ese wa si,
At’ ile Re t’ O ko sihin.
S’ odo Re t’ a ti ko sile;
Jo, da ilu ese wa si,
At’ ile Re t’ O ko sihin.
3. Or’-ofe Re lie be wa,
Eje Omo Re l’a mu wa,
Ileri Re ni k’ O ranti,
Gbogbo ‘wonyi ko ha to bi?
Eje Omo Re l’a mu wa,
Ileri Re ni k’ O ranti,
Gbogbo ‘wonyi ko ha to bi?
4. Ebe nip’ or’-ofe wonyi,
Ti m’ opo ‘bukun sokale,
S’ ori ile t’ o kun f’ ese;
Jeki nwon le gba wa pelu.
Ti m’ opo ‘bukun sokale,
S’ ori ile t’ o kun f’ ese;
Jeki nwon le gba wa pelu.
Tip: double-tap the words (or use ) to show them full screen on a projector or TV.
Sing to the tune of
Any of these hymns' tunes fits YBH 468.