YBH 465

Afrik’ ‘le wara at’ oyin

Save
1. Afrik’ ‘le wara at’ oyin,
Ni orile aiye nwo si,
T’ Olorun fun ania dudu,
Fun ini re titi lailai.
2. Ote owo-eru ‘gbani,
Ko f’ okan baba wa bale,
A ko won lo lairotele,
Nwon s’ eru, oju si pon won.
3. Ose at’ ekun gb’ ile kan,
Gb’ oko, aya, baba, omo,
Fi tulasi, ‘daro, pinya,
At’ edun t’ enu ko le so.
4. Sugbon b’ Olorun Olore
Ti ranti Israel nigbani,
O s’ona igbala fun won,
Nwon d’ omnira, omo Kristi.
5. Sibe opo gbagbe ‘le won,
Oluwa a mbe, se ‘ranwo,
Mu won pada si ile won;
Ka si le tubo ma yin O.
6. Eko, ‘laju ‘gbagbo pipe,
Irepo at’ ife toto,
Rojo won lat’ odo Re wa,
S’ ori gbogbo ‘le Afrika.
7. Oluwa Olodumare,
Je k’ ile wa wulo fun wa,
Gbati ‘se wa l’aiye ba pin,
Gba wa s’ orun alafia.

Tip: double-tap the words (or use ) to show them full screen on a projector or TV.

My melodies

Found another hymn whose tune fits this one? Save it here so you can sing it again.

Sign in to save melodies

Sources: acknowledgements.

Take FaceChrist everywhere

Chat, post, meet people and sell from your phone. Get instant alerts for new messages and matches, plus the Bible offline in seven languages.