Bi mo ti ri - laisawawi
1. Bi mo ti ri - laisawawi,
Sugbon nitori eje Re,
B’O si ti pe mi pe ki nwa -
Olugbala, mo de.
Sugbon nitori eje Re,
B’O si ti pe mi pe ki nwa -
Olugbala, mo de.
2. Bi mo ti ri - laiduro pe,
Mo fe k’okan mi mo toto,
Sodo Re t’o le we mi mo.
Olugbala, mo de.
Mo fe k’okan mi mo toto,
Sodo Re t’o le we mi mo.
Olugbala, mo de.
3. Bi mo ti ri -b’o tile je
Ija l’ode, ija ninu;
Eru l’ode, eru ninu -
Olugbala, mo de.
Ija l’ode, ija ninu;
Eru l’ode, eru ninu -
Olugbala, mo de.
4. Bi mo ti ri -osi, are,
Mo si nwa imularada;
Iwo l’o le s’awotan mi -
Olugbala, mo de.
Mo si nwa imularada;
Iwo l’o le s’awotan mi -
Olugbala, mo de.
5. Bi mo ti ri -‘wo o gba mi,
‘wo o gba mi t’owo t’ese
‘Tori mo gba ‘leri Re gbo -
Olugbala, mo de.
‘wo o gba mi t’owo t’ese
‘Tori mo gba ‘leri Re gbo -
Olugbala, mo de.
6. Bi mo ti ri - ife Tire
L’ o sele mi patapata;
Mo di Tire, Tire nikan -
Olugbala, mo de.
L’ o sele mi patapata;
Mo di Tire, Tire nikan -
Olugbala, mo de.
Tip: double-tap the words (or use ) to show them full screen on a projector or TV.