B’AIYE mi kun fun ‘banuje
1. B’AIYE mi kun fun ‘banuje,
O dara, o te mi l’orun;
Laikun mo nreti ipe Re,
Gbogbo nkan ni emi ntoro.
O dara, o te mi l’orun;
Laikun mo nreti ipe Re,
Gbogbo nkan ni emi ntoro.
2. Emi kio wa ayokayo,
Lehin ki nle se ife Re,
Kio wa ‘ranwo ninu lala,
Lehin eyit’O le fun mi
Lehin ki nle se ife Re,
Kio wa ‘ranwo ninu lala,
Lehin eyit’O le fun mi
3. Aiye l’opin: k’a ma jeki
Aniyan aiye gb’okan wa;
Tire ni lati ka ‘jo wa,
Tiwa lati fi won yin O.
Aniyan aiye gb’okan wa;
Tire ni lati ka ‘jo wa,
Tiwa lati fi won yin O.
4. Igbagbo nikan n’ise wa,
Igbagbo t’o duro sinsin;
Ojo na ti l’abukun to,
T’ awon enia Re fi sin O.
Igbagbo t’o duro sinsin;
Ojo na ti l’abukun to,
T’ awon enia Re fi sin O.
Tip: double-tap the words (or use ) to show them full screen on a projector or TV.
Sing to the tune of
Any of these hymns' tunes fits YBH 333.